29. Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún ọ, ìbáà ṣe rere tàbí búburú.
30. Nísin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ lati padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?”
31. Jákọ́bù dá Lábánì lóhùn pé, “Ẹ̀rù ni ó bà mi nítorí, mo rò pé ìwọ le fi tipá tipá gba àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ mi.”
32. “Ṣùgbọ́n bí o bá ri ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ère rẹ, kí ẹni náà di òkú.” Ó tún wí pé, “Níwájú gbogbo ìbátan wa báyìí, wò ó fúnra rẹ, bí o bá rí ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ, mú un.” Jákọ́bù kò sì mọ̀ pé, Rákélì ni ó jí àwọn òrìṣà náà.
33. Lábánì sì lọ sínú àgọ́ Jákọ́bù àti ti Líà àti ti àwọn ìránṣẹ́-bìnrin méjèèjì, kò sì rí ohunkóhun. Lẹ́yìn ìgbà tí ó jáde nínú àgọ́ Líà ni ó lọ sí àgọ́ Rákélì.
34. Rákélì sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ràkunmí, ó sì jókòó lé e lórí. Lábánì sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun.
35. Rákélì sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ bàbá à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.” Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà-ìdílé náà.
36. Inú sì bí Jákọ́bù, ó sì pe Lábánì ní ìjà pé, “Kín ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ tí ìwọ fi ń lépa mi bí ọ̀daràn?
37. Nísinsin yìí tí ìwọ ti tú gbogbo ẹrù mi wò, kín ni ohun tí í ṣe tirẹ̀ tí ìwọ rí? Kó wọn kalẹ̀ báyìí níwájú gbogbo ìbátan rẹ àti tèmi, kí wọn kí ó sì ṣe ìdájọ́ láàrin àwa méjèèjì.
38. “Mo ti wà lọ́dọ̀ rẹ fún ogún ọdún, àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rẹ kò sọnù bẹ́ẹ̀ n kò pa ọ̀kan jẹ rí nínú àwọn àgbò rẹ.