Jẹ́nẹ́sísì 21:2-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ṣárà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan-an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un.

3. Ábúráhámù sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sárà bí fun un ní Ísáákì.

4. Nígbà tí Ísáákì pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Ábúráhámù sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún-un.

5. Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ábúráhámù nígbà tí ó bí Ísáákì.

6. Ṣárà sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.”

7. Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Ábúráhámù pé, Ṣárà yóò di ọlọ́mọ? Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Ábúráhámù ní ìgbà ogbó rẹ.”

8. Nígbà tí ọmọ náà dàgbà ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Ísáákì lẹ́nu ọmú, Ábúráhámù ṣe àsè ńlá.

9. Ṣùgbọ́n Ṣárà rí ọmọ Ágárì ará Éjíbítì tí ó bí fún Ábúráhámù tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà,

10. ó sì wí fún Ábúráhámù pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Ísáákì pín ogún.”

11. Ọ̀rọ̀ náà sì ba Ábúráhámù lọ́kàn jẹ́ gidigidi nítorí ọmọ rẹ̀ náà sáà ni Isìmàẹ́lì i ṣe.

12. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fun un pé, “Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ. Gbọ́ ohun tí Ṣárà wí fún ọ, nítorí nípasẹ̀ Ísáákì ni a ó ti ka irú ọmọ rẹ̀.

13. Èmi yóò sọ ọmọ ẹrúbìnrin náà di orílẹ̀ èdè pẹ̀lú, nítorí ọmọ rẹ ni.”

14. Ábúráhámù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mú oúnjẹ àti ìgò omi kan, ó sì kó wọn fún Ágárì, ó kó wọn lé e léjìká, ó sì lé e jáde pẹ̀lú ọmọ náà. Ó sì lọ lọ́nà rẹ, ó sì ń ṣe alárìnkiri ní ijù Báá-Ṣébà.

15. Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó.

16. Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà (bí i ogójì míta), nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún.

17. Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Ańgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Ágárì láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Ágárì, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Olúwa ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí.

18. Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dì í mú (tùú nínú) nítorí èmi yóò ṣọ ọmọ náà di orilẹ̀ èdè ńlá.”

Jẹ́nẹ́sísì 21