8. Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà bálì, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pómégíránátì, òróró ólífì àti oyin.
9. Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá.
10. Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin Olúwa Ọlọ́run yín fún pípèṣè ilẹ̀ rere fún un yín.
11. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.
12. Kí ó má baà jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀,
13. nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i,
14. nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbé ga, tí ẹ ó sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá, nínú oko ẹrú.
15. Òun ni ó mú un yín la ihà ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òùngbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńláńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.
16. Ó fún yín ní mánà láti jẹ nínú ihà, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun báà le tẹ orí i yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó báà lè dára fún-un yín.
17. Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.”
18. Ṣùgbọ́n ẹ rántí Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fún un yín lókun àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí.
19. Bí ẹ bá wá gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn, tí ẹ sì sìn wọ́n, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, Mo kìlọ̀ fún un yín pé rírun ni ẹ ó run.
20. Bí àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa parun níwájú u yín, bákan náà ni ẹ ó parun, torí pé ẹ kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín lẹ́nu.