Sáàmù 70 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àdúrà Ìdáǹdè Kúrò Lọ́wọ́ Ọ̀ta

1. Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là, Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

2. Kí àwọn tí ń wá ọkàn mikí a dojú tì wọ́n, kí wọn sì dààmú;kí àwọn tó ń wá ìparun miyí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.

3. Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrèìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Áà! Áà!”

4. Ṣùgbọ́n kí àwọn tí o ń wà ọ ó máa yọ̀kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa Rẹ,kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà Rẹ máa wí pé,“Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

5. Ṣíbẹ̀ mo jẹ́ òtòsì, mo sì jẹ́ aláìní;wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùtúsílẹ̀ mi; Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.