Sáàmù 114 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ọlọ́run Ti Ń Gba Ni

1. Nígbà tí Ísírẹ́lì jáde ní Éjíbítì,ilé Jákọ́bù láti inú ènìyàn àjòjì èdè

2. Júdà wà ní ibi mímọ́,Ísírẹ́lì wà ní ìjọba.

3. Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:Jódáni sì padà sẹ́yìn.

4. Àwọn òkè ńlá ń fò bí agbo àtiòkè kékèké bí ọ̀dọ́ àgùntàn.

5. Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ òkun, tí ìwọ fi wárìrì?Ìwọ Jódánì, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?

6. Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí agbo,àti ẹ̀yin òkè kékèké bí ọ̀dọ́ àgùntàn?

7. Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;ní iwájú Ọlọ́run Jákọ́bù

8. tí ó sọ àpáta di adágún omi,àti òkúta-ìbọn di orísun omi.