Sáàmù 117 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ yin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀ èdè;ẹ pòkìkí Rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.

2. Nítorí ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ tí ó ní sí wa,àti òtítọ́ Olúwa dúró láéláé.Ẹ yin Olúwa!