Sáàmù 134 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ kíyèsí i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.

2. Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́,kí ẹsì fi ìbùkún fún Olúwa.

3. Olúwa tí ó dá ọ̀run Òun ayé,kí ó bùsí i fún ọ láti Síónì wá.