Jẹ́nẹ́sísì 8:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Nóà sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀.

7. Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti ṣẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀.

8. Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Nóà. Nóà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀.

10. Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀.

11. Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àsáálẹ́, ó já ewé igi ólífì tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Nóà mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀.

12. Nóà tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.

13. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Nóà sì sí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ.

14. Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ilẹ̀ ti gbẹ pátapáta.

15. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Nóà pé.

16. “Jáde kúrò nínú ọkọ̀, ìwọ àti aya rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti àwọn aya wọn.

17. Kó gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú rẹ jáde: àwọn ẹyẹ, ẹranko àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀, kí wọn lè bí sí i, kí wọn sì pọ̀ sí i, kí wọn sì máa gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀.”

18. Nóà, àwọn ọmọ rẹ̀, aya rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì jáde.

19. Gbogbo àwọn ẹranko àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀ àti gbogbo ẹyẹ pátapáta ni ó jáde kúrò nínú ọkọ̀, ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní irú tiwọn.

20. Nóà sì mọ pẹpẹ fún Olúwa, ó sì mú lára àwọn ẹran tí ó mọ́ àti ẹyẹ tí ó mọ́, ó sì fi rúbọ ṣísun lórí pẹpẹ.

Jẹ́nẹ́sísì 8