Jẹ́nẹ́sísì 40:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ ọba Éjíbítì, olúwa wọn.

2. Fáráò sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè,

3. Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀sọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Jósẹ́fù pẹ̀lú wà.

4. Olórí ẹ̀sọ́ sì yan Jósẹ́fù láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn.Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀.

5. Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà-olórí agbọ́tí àti olórí alásè lá àlá, ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.

6. Nígbà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn.

7. Ó sì bi àwọn ìjòyè Fáráò tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?”

8. Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.”Jósẹ́fù sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtúmọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.”

9. Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Jósẹ́fù, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi,

10. Mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n.

11. Ife Fáráò sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èṣo àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Fáráò, mo sì gbé ife náà fún Fáráò.”

12. Jósẹ́fù wí fún-un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta.

Jẹ́nẹ́sísì 40