17. Káínì sì bá aya rẹ̀ lò pọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Énókù. Káínì sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Énókù sọ ìlú náà.
18. Énókù sì bí Írádì, Írádì sì ni baba Méhújáélì, Méhújáélì sì bí Métúsáélì, Métúsáélì sì ni baba Lámékì.
19. Lámékì sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkíní ni Ádà, àti orúkọ èkejì ni Ṣílà.
20. Ádà sì bí Jábálì: òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran-ọ̀sìn.
21. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Júbálì, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè.
22. Ṣílà náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Káínì, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Káínì ni Náámà.
23. Lámékì wí fún àwọn aya rẹ̀,“Ádà àti Ṣílà, ẹ tẹ́tí sí mi;ẹ̀yin aya Lámékì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí,ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára.
24. Bí a ó bá gbẹ̀san Káínì ní ìgbà méje,ǹjẹ́ kí a gba ti Lámékì nígbà àádọ́rin-lé-méje.”
25. Ádámù sì tún bá aya rẹ̀ lò pọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣẹ́tì, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Ábélì tí Káínì pa.”
26. Ṣẹ́tì náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Énọ́sì.Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ Olúwa.