Deutarónómì 9:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì. Báyìí, ẹ ti gbáradì látí la Jọ́dánì kọjá, láti lọ gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ, tí wọ́n ní àwọn ìlú ńláńlá, tí odi wọn kan ọ̀run.

2. Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga àní àwọn ọmọ Ánákì ni wọ́n. Ẹ gbọ́ nípa wọn, ẹ sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa wọn pé, “Ta ni ó le è dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Ánákì (Òmìrán)?”

3. Ṣùgbọ́n kí ó dá a yín lójú lónìí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ń ṣáájú u yín lọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun. Yóò jó wọn run, yóò sì tẹ orí wọn ba níwájú yín. Ẹ ó sì lé wọ́n jáde, ẹ ó sì run wọ́n kíákíá, bí Olúwa ti ṣèlérí fún un yín.

4. Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti lé wọn jáde níwájú u yín, ẹ má ṣe wí fún ara yín pé, “Torí òdodo mi ní Olúwa se mú mi wá síbí láti gba ilẹ̀ náà.” Rárá, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ni Ọlọ́run yóò se lé wọn jáde níwájú u yín.

5. Kì í se nítorí òdodo yín, tàbí ìdúróṣinṣin ni ẹ ó fí wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ: fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù.

6. Ṣùgbọ́n kí ó yé yín pé kì í ṣe nítorí òdodo yín ni Olúwa Ọlọ́run yín fi ń fún un yín ní ilẹ̀ rere náà, láti ní, nítorí pé alágídí ènìyàn ni ẹ jẹ́.

7. Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ ti mú Olúwa Ọlọ́run yín bínú ní ihà. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Éjíbítì ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa títí tí ẹ fi dé ìhín yìí.

8. Ní Hórébù ẹ mú kí Olúwa bínú, títí débi pé ó fẹ́ run yín.

9. Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba sílétì òkúta, sílétì májẹ̀mú ti Olúwa ti bá a yín dá. Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mumi.

10. Olúwa fún mi ní òkúta méjì tí a fi ìka Ọlọ́run kọ. Lórí wọn ni a kọ àwọn òfin tí Ọlọ́run sọ fún un yín lórí òkè láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ sí.

11. Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, Olúwa fún mi ní sílétì òkúta méjì, sílétì òkúta májẹ̀mú náà.

12. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìnín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Éjíbítì ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kíá, nínú àṣẹ mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.”

13. Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé alágídí ènìyàn gbáà ni wọ́n.

14. Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀ jù wọ́n lọ.”

15. Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí okè náà wá, orí òkè tí o ń yọná. Àwọn sílétì májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi.

16. Gbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un yín.

Deutarónómì 9