Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ ti mú Olúwa Ọlọ́run yín bínú ní ihà. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Éjíbítì ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa títí tí ẹ fi dé ìhín yìí.