Deutarónómì 33:15-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanìàti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;

16. Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Jósẹ́fù,lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀.

17. Ní ọlá ńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀ èdè,pàápàá títí dé òpin ayé.Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún Éfúráímù,àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè.”

18. Ní ti Ṣébúlúnì ó wí pé:“Yọ̀ Sébúlúnì, ní ti ìjáde lọ rẹ,àti ìwọ Ísákárì, nínú àgọ́ rẹ.

19. Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkèàti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkun,nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”

20. Ní ti Gádì ó wí pé:“Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gádì gbilẹ̀!Gádì ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,ó sì fa apá ya, àní àtàrí.

21. Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;ìpín olórí ni a sì fi fún un.Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,ó mú òdodo Olúwa se,àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”

22. Ní ti Dánì ó wí pé:“Ọmọ kìnnìún ni Dánì,tí ń fò láti Básánì wá.”

23. Ní ti Náfítánì ó wí pé,“Ìwọ Náfítánì, Náfítánì kún fún ojú rere Ọlọ́runàti ìbùkún Olúwa;yóò jogún ìhà ìwọ̀ oòrùn àti gúṣù.”

24. Ní ti Áṣérì ó wí pé:“Ìbùkún ọmọ ni ti Áṣérì;jẹ́ kí ó rí ojú rere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀kí ó sì ri ẹṣẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.

25. Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ,agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.

26. “Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jéṣúrúnì,ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹàti ní ojú ọ̀run nínú ọlá ńlá rẹ̀.

27. Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ,àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà.Yóò lé àwọn ọ̀ta rẹ níwájú rẹ,ó sì wí pé, ‘Ẹ máa párun!’

28. Ísírẹ́lì nìkan yóò jòkòó ní àlàáfíà,oríṣun Jákọ́bù nìkanní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì,níbi tí ọ̀run ti ń ṣẹ ìrì sílẹ̀.

29. Ìbùkún ni fún ọ, Ísírẹ́lì,ta ni ó dà bí ì rẹ,ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?Òun ni àṣà àti ìrànwọ́ rẹ̀àti idà ọlá ńlá rẹ̀.Àwọn ọ̀ta rẹ yóò tẹríba fún ọ,ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”

Deutarónómì 33