Deutarónómì 10:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. (Àwọn ará Ísírẹ́lì sì gbéra láti kàǹga àwọn ará a Jákánì dé Mósérà. Níbí ni Árónì kú sí, tí a sì sin ín, Élíásárì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà.

7. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rìn lọ sí Gúdígódà, títí dé Jótíbárà, ilẹ̀ tí o kún fún odò tí ó ń sàn.

8. Ní ìgbà yí ni Olúwa yan àwọn ọmọ Léfì láti máa ru àpótí májẹ̀mú Olúwa, láti máa dúró níwájú Olúwa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ Olúwa súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí.

9. Ìdí nìyí tí àwọn ẹ̀yà Léfì kò fi ní ìpín tàbí ogún kan láàrin àwọn arákùnrin wọn. Olúwa ni ogún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti sọ fún un yín.)

10. Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, Olúwa sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín.

11. Olúwa sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn báà lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.”

12. Nísinsin yìí ìwọ Ísírẹ́lì, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkan àti àyà rẹ,

13. àti láti máa kíyèsí àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ire ara à rẹ.

14. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.

15. Ṣíbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀ èdè títí di òní.

16. Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, (Ẹ wẹ ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́) kí ẹ má sì se jẹ́ olóríkunkun mọ́ láti òní lọ.

17. Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojú ṣàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

Deutarónómì 10