Ámósì 9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

A Ó Pa Ísírẹ́lì Run.

1. Mo rí Olúwa, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé:“Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùnkí àwọn òpó kí ó lè mìfọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyànàwọn tí ó sẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa,Ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbéẸni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà.

2. Bí wọ́n tilẹ wa ilẹ lọ sí ìpò òkúLáti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́nBí wọ́n tilẹ̀ gun òkè ọ̀run lọ,láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀kalẹ̀.

3. Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Kámẹ́lì,èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀.Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìṣàlẹ̀ òkun,láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán.

4. Bí wọ́n tilẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní iwájú àwọn ọ̀tá wọnláti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà kí ó ṣá wọn pa.Èmi yóò sì tẹ ojú mi mọ́ wọn fún ìbí,kì í sì í se fún rere.”

5. Olúwa, Ọlọ́run AlágbáraẸni ti ó fi ọwọ́ kan ìlẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì sọ̀fọ̀Gbogbo orílẹ̀ èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Náìlìti wọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Éjíbítì.

6. Òun ni ẹni tí ó kọ́ itẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀runti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayéẸni ti ó pe àwọn omi òkunti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé Olúwa ni orúkọ rẹ̀.

7. “Àbá ẹyin ọmọ Ísírẹ́lìkò ha dàbí àwọn ọmọ Kúsì sí mi?”ni Olúwa wí.“Èmi kò ha ti mú Ísírẹ́lì gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì jáde wáàti àwọn Fílístínì láti ilẹ̀ Káfítórìàti àwọn Árámú láti kírì?

8. “Dájúdájú, ojú Olúwa Ọlọ́run ń bẹ̀lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀.Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀Ṣíbẹ̀ Èmi kò ni pa ilé Jákọ́bù run pátapáta,”ni Olúwa wí.

9. “Nítorí Èmi yóò pàṣẹ,Èmi yóò sì mi ilé Ísírẹ́lìní àárin àwọn orílẹ̀ èdèbí a ti ń jọ ọkàn nínú ajọ̀tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀.

10. Gbogbo àwọn ẹlẹ́sẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn mini yóò ti ipa idà kúgbogbo àwọn ti ń wí péAburú kì yóò lé wa bá,bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́?A mú Ísírẹ́lì padà bọ̀ sípò.

Ìmúpadàbọ̀ Ísírẹ́lì

11. “Ní ọjọ́ náà ní Èmi yóò gbéàgọ́ Dáfídì tí ó wó róÈmi yóò mọ odi rẹ̀ tí ó wóÈmi yóò sì sọ ahoro rẹ̀ di ìlúÈmi yóò sì kọ bí ó ti wà tẹ́lẹ̀

12. kí wọn le jógun ìyókù Édómùàti gbogbo orílẹ̀ èdè ti ń jẹ́ orúkọ mi,”ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.

13. “Ọjọ́ náà ń bọ,” ni Olúwa wí,“Tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè báTí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn báÀwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀Tí yóò sì ṣàn láti ara àwọn òkè kékèké.

14. Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Ísírẹ́lì ènìyàn mi padà bọ̀Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọnWọn yóò sì gbin àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọnwọn yóò sì se ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn

15. Èmi yóò gbin Ísírẹ́lì sí orí ilẹ̀ rẹ̀.A kì yóò sì fà wọn tu mọ́ láéláékúrò ni orí ilẹ̀ ti mo fi fún wọn,”ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wí.