3. Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í se ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè.
4. Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìyìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í se bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò se Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò.
5. A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa.
6. A kò bèèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí àpósítélì Kírísítì a ò bá ti di àjàgà fún un yín.
7. Ṣùgbọ́n àwa se pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrin yín tí a sì se ìtọ́jú yín gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
8. A fẹ́ràn yín púpọ̀, èyí ló mu kí ó ṣe é ṣe fún wa láti pín ìyìnrere náà fún yín pẹ̀lú ìgbésí ayé àwa pàápàá.
9. Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn-án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnìkẹ́ni bí a ti ń wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín.
10. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrin ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.
11. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀
12. ìyànjú, ìtùnnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkararẹ̀.
13. Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.
14. Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́se àwọn ìjọ tí o wà ní Jùdíà jẹ. Bí a ti gbógun tì wọ́n, láti ọwọ́ àwọn ará ìlú wọn (àwọn Júù), bẹ́ẹ̀ ni a gbógun ti ẹ̀yin pàápàá láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù,
15. àwọn tí wọ́n pa Jésù Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn
16. nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìyìnrere dúró láàrin àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀sẹ̀ wọn ń di púpọ̀ síi lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.