Jòhánù 13:26-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Nítorí náà Jésù dáhùn pé, “Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo.” Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Júdásì Ísíkárótù ọmọ Símónì.

27. Ní kété tí Júdásì gba àkàrà náà ni Sátanì wọ inú rẹ̀ lọ.Nítorí náà Jésù wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń se nì, yára ṣe é kánkán.”

28. Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un.

29. Nítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nitorí Júdásì ni ó ni àpò, ni Jésù fi wí fún un pé, Ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà; tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn talákà.

30. Nígbà tí ó sì ti gbà òkèlè náà tan, ó jáde lójúkan náà: òru sì ni.

31. Nítorí náà nígbà tí ó jáde lọ tan, Jésù wí pé, “Nísinsìn yìí ni a yin ọmọ-ènìyàn lógo, a sì yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀.

32. Bí a bá yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀, Ọlọ́run yóò sì yìn ín lógo nínú òun tìkára rẹ̀, yóò sì yìn ín lógo nísinsìn yìí.

33. “Ẹ̀yin ọmọ mi, nígbà díẹ̀ sí i ni èmi wà pẹ̀lú yín. Ẹ̀yin ó wá mi: àti gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún àwọn Júù pé, Níbití èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì ó le wà; bẹ́ẹ̀ ni mo sì wí fún yín nísìnsìn yìí.

34. “Òfin titun kan ni mo fi fún yín, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ ọmọnìkejì yín; gẹ́gẹ́ bí èmi ti fẹ́ràn yín, kí ẹ̀yin kí ó sì lè fẹ́ràn ọmọnìkejì yín.

35. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin ń se, nígbà tí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ sí ọmọ ẹnìkejì yín.”

36. Símónì Pétérù wí fún un pé, “Olúwa, níbo ni ìwọ ń lọ?”Jésù dá a lóhùn pé, “Níbi tí èmi ń lọ, ìwọ kì yóò lè tọ̀ mí nísinsin yìí; ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ̀ mí níkẹyìn.”

Jòhánù 13