8. Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Éjíbítì. Fáráò rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtúmọ̀ àlá náà fún un.
9. Nígbà náà ni olórí agbọ́tí wí fún Fáráò pé, “Lónìí ni mo rántí àìṣedéédé mi.
10. Nígbà kan tí Fáráò bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi èmi àti olórí alásè sínú ẹ̀wọn ní ilé olórí ẹ̀sọ́.
11. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lá àlá, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.
12. Ọmọkùnrin ará Hébérù kan tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀sọ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. A ṣọ́ àwọn àlá wa fún un, ó sì túmọ̀ wọn fún wa, ó sọ ìtúmọ̀ àlá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un.
13. Bí ó sì ti túmọ̀ àlá wọ̀nyí náà ni ohun gbogbo rí. A dá mi padà sí ipò mi, a sì ṣo ọkùnrin keji kọ́ sórí òpó.”
14. Nítorí náà Fáráò ránṣẹ́ pe Jósẹ́fù, wọn sì mu un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, s tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá ṣíwájú Fáráò.
15. Fáráò wí fún Jósẹ́fù, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀”
16. Jóṣẹ́fù dáhùn pé, “kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fún Fáráò ní ìtúmọ̀ àlá náà.”
17. Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jóṣẹ́fu pé, “Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Náílì,
18. sì kíyèsí i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀.
19. Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógo, wọn kò sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí n kò tíì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Éjíbítì.