Ọmọkùnrin ará Hébérù kan tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀sọ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. A ṣọ́ àwọn àlá wa fún un, ó sì túmọ̀ wọn fún wa, ó sọ ìtúmọ̀ àlá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un.