Jẹ́nẹ́sísì 40:12-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Jósẹ́fù wí fún-un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta.

13. Láàrin ọjọ́ mẹ́ta Fáráò yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbọ́tí fún-un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá.

14. Ṣùgbọ́n nígbà tí ohun gbogbo bá dára fún ọ, rántí mi kí o sì fi àánú hàn sí mi. Dárúkọ mi fún Fáráò, kí o sì mú mi jáde kúrò ní ìhín.

15. Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Ébérù ni, àti pé níhìnín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí.”

16. Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtúmọ̀ tí Jósẹ́fù fún àlá náà dára, ó wí fún Jósẹ́fù pé, “Èmi pẹ̀lú lá àlá: Mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí,

17. Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Fáráò, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi”

18. Jósẹ́fù dáhùn, “Èyí ni ìtúmọ̀ àlá rẹ. Agbọ̀n mẹ́ta náà túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta.

19. Láàrin ọjọ́ mẹ́ta, Fáráò yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi. Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ.”

20. Ọjọ́ kẹ́ta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Fáráò, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí aláṣè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n.

21. Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí i ti àtẹ̀yìnwa,

22. Ṣùgbọ́n, ó so olórí alásè kọ́ sórí igi, gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ti sọ fún wọn nínú ìtúmọ̀ rẹ̀ sí àlá wọn.

Jẹ́nẹ́sísì 40