Jẹ́nẹ́sísì 26:23-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Bíáṣébà.

24. Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fara hàn-án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù baba rẹ: Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Ábúráhámù ìránṣẹ́ mi.”

25. Ísáákì sì kọ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan ṣíbẹ̀.

26. Nígbà náà ni Ábímélékì tọ̀ ọ́ wá láti Gérárì, àti Áhúsátì, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fíkólì, olórí ogun rẹ̀.

27. Ísáákì sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yin?”

28. Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrin àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn

29. pé ìwọ kì yóò ṣe wá ní ibi, bí àwa pẹ̀lú kò ti ṣe ọ́ ní aburú, tí a sì ń ṣe ọ́ dáradára, tí a sì rán ọ jáde ní àlàáfíà láì ṣe ọ́ ní ibi, kíyèsi Olúwa sì ti bùkún fún ọ.”

30. Ísáákì sì ṣe àsè fún wọn, wọn sì jẹ, wọ́n sì mu.

31. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọn búra fún ara wọn. Ísáákì sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ ní àlàáfíà.

32. Ní ọjọ́ náà gan-an ni àwọn ìránṣẹ́ Ísáákì wá sọ fún un pé àwọn ti kan omi ní kànga kan tí àwọn gbẹ́.

33. Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣébà (kànga májẹ̀mu), títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Bíáṣébà.

34. Nígbà tí Ísọ̀ pé ọmọ ogójì ọdún (40) ó fẹ́ ọmọbìnrin kan tí a ń pè ní Júdíìtì, ọmọ Béérì, ará Hítì, ó sì tún fẹ́ Báṣémátì, ọmọ Élónì ará Hítì.

35. Fífẹ́ tí a fẹ́ àwọn obìnrin wọ̀nyí jẹ́ ìbànújẹ́ fún Ísáákì àti Rèbékà.

Jẹ́nẹ́sísì 26