16. Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà (bí i ogójì míta), nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún.
17. Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Ańgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Ágárì láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Ágárì, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Olúwa ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí.
18. Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dì í mú (tùú nínú) nítorí èmi yóò ṣọ ọmọ náà di orilẹ̀ èdè ńlá.”
19. Ọlọ́run sì ṣí ojú Ágárì, ó sì rí kànga kan, ó lọ ṣíbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu.
20. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ìjù, ó sì di tafàtafà.
21. Nígbà tí ó ń gbé ni ihà ní Páránì, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.
22. Ní àkókò yìí ni ọba Ábímélékì àti Píkólì, olórí ogun rẹ̀ wí fún Ábúráhámù pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe.
23. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fi hàn fún ọ pẹ̀lú.”
24. Ábúráhámù sì wí pé, “Èmí búra.”
25. Nígbà náà ni Ábúráhámù fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Ábímélékì nípa kànga tí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀.
26. Ṣùgbọ́n Ábímélékì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe èyí, ìwọ kò sì sọ fún mi tẹ́lẹ̀, òní ni mo sẹ̀sẹ̀ ń gbọ́ báyìí.”
27. Ábúráhámù sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Ábímélékì. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú.
28. Ábúráhámù sì ya abo ọ̀dọ́-àgùtàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀.
29. Ábímélékì sì béèrè lọ́wọ́ Ábúráhámù pé, “Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí.”