Jẹ́nẹ́sísì 21:11-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ọ̀rọ̀ náà sì ba Ábúráhámù lọ́kàn jẹ́ gidigidi nítorí ọmọ rẹ̀ náà sáà ni Isìmàẹ́lì i ṣe.

12. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fun un pé, “Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ. Gbọ́ ohun tí Ṣárà wí fún ọ, nítorí nípasẹ̀ Ísáákì ni a ó ti ka irú ọmọ rẹ̀.

13. Èmi yóò sọ ọmọ ẹrúbìnrin náà di orílẹ̀ èdè pẹ̀lú, nítorí ọmọ rẹ ni.”

14. Ábúráhámù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mú oúnjẹ àti ìgò omi kan, ó sì kó wọn fún Ágárì, ó kó wọn lé e léjìká, ó sì lé e jáde pẹ̀lú ọmọ náà. Ó sì lọ lọ́nà rẹ, ó sì ń ṣe alárìnkiri ní ijù Báá-Ṣébà.

15. Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó.

16. Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà (bí i ogójì míta), nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún.

17. Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Ańgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Ágárì láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Ágárì, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Olúwa ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí.

18. Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dì í mú (tùú nínú) nítorí èmi yóò ṣọ ọmọ náà di orilẹ̀ èdè ńlá.”

19. Ọlọ́run sì ṣí ojú Ágárì, ó sì rí kànga kan, ó lọ ṣíbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu.

20. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ìjù, ó sì di tafàtafà.

21. Nígbà tí ó ń gbé ni ihà ní Páránì, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.

22. Ní àkókò yìí ni ọba Ábímélékì àti Píkólì, olórí ogun rẹ̀ wí fún Ábúráhámù pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe.

23. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fi hàn fún ọ pẹ̀lú.”

Jẹ́nẹ́sísì 21