Jẹ́nẹ́sísì 15:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Olúwa sì mú Ábúrámù jáde síta ó sì wí fún un pé, “Gbójú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀-bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú ọmọ rẹ yóò rí.”

6. Ábúrámù sì gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sì òdodo fun-un.

7. Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Úrì ti Kálídéà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”

8. Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, “Olúwa Ọlọ́run, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”

9. Nítorí náà, Olúwa wí fún-un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́tamẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”

10. Ábúrámù sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjìméjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣugbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn.

11. Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Ábúrámù sì ń lé wọn.

12. Bí oòrùn ti ń wọ̀, Ábúrámù sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó.

Jẹ́nẹ́sísì 15