Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13:26-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. “Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Ábúráhámù, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí.

27. Nítorí àwọn tí ń gbé Jerúsálémù, àti àwọn olórí wọn, nítorí ti wọn kò mọ̀ Jésù, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi.

28. Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pílátù láti pá a.

29. Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀we nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì.

30. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú,

31. Ó sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Gálílì wá sí Jerúsálémù, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsìn yìí fún àwọn ènìyàn.

32. “Àwa sì mú ìyìn rere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa,

33. Èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jésù dìde: Bí a sì ti kọwé rẹ̀ nínú Sáàmù kejì pé:“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;lónìí ni mo bí ọ.’

34. Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyí pé:“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dáfídì, tí ó dájú.’

35. Nítorí ó sì wí nínú Sáàmù mìíràn pẹ̀lú pé:“ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’

36. “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dáfídì ti sin ìran rẹ tan nípa Ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13