Ìṣe Àwọn Àpósítélì 10:39-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. “Àwa sì ni ẹlẹ́rì gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerúsálémù. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi.

40. Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba.

41. Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti lọ́wọ́ Ọlọ́run yàn tẹ́lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jindé kúrò nínú òkú.

42. Ó sì paṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe Onídàjọ́ ààyè àti òkú.

43. Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.”

44. Bí Pétérù sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.

45. Ẹnu sì yà àwọn onígbàgbọ́ ti ìkọlà tí wọ́n bá Pétérù wá, nítorí ti a tu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ sórí àwọn aláìkọlà pẹ̀lú.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 10