Deutarónómì 27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Pẹpẹ Ní Orí Òkè Ébálì.

1. Mósè àti àwọn àgbà Isírẹ́lì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé: “Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́.

2. Nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì sí inú ilẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbékalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun.

3. Kí o kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí o bá ti ń ré kọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ.

4. Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ébálì, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun.

5. Kọ́ Pẹpẹ ṣíbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn.

6. Kí o kọ́ pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú òkúta nínú pápá kí o sì sun ẹbọ ni orí i rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ.

7. Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

8. Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”

Ègún Ní Orí Òkè Ébálì.

9. Nígbà náà ni Móṣè àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, sọ fún Ísírẹ́lì pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Ísírẹ́lì, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí.

10. Gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”

11. Ní ọjọ́ kan náà Móṣè pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.

12. Nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gérísímù láti ṣúre fún àwọn ènìyàn: Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì, Jóṣẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.

13. Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ébálì láti gé ègún: Rúbẹ́nì, Gádì, àti Ásérì, àti Ṣébúlúnì, Dánì, àti Náfitanì.

14. Àwọn ẹ̀yà Léfì yóò ké sí gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì ní ohùn òkè:

15. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ onísọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

16. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójú ti baba tàbí ìyá rẹ̀”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

17. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládúgbò o rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

18. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó si afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

19. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àléjò, aláìní baba tàbí opó”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

20. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

21. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbalòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

22. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá a rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

23. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

24. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

25. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

26. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa síse wọ́n.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”