10. Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, Olúwa sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín.
11. Olúwa sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn báà lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.”
12. Nísinsin yìí ìwọ Ísírẹ́lì, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkan àti àyà rẹ,
13. àti láti máa kíyèsí àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ire ara à rẹ.
14. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.
15. Ṣíbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀ èdè títí di òní.
16. Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, (Ẹ wẹ ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́) kí ẹ má sì se jẹ́ olóríkunkun mọ́ láti òní lọ.
17. Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojú ṣàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
18. Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àlejò, Óun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn.
19. Ẹ gbọ́dọ̀ fẹ́ràn àwọn àlejò, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àlejò rí ní Éjíbítì.
20. Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dì í mú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀.
21. Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí.
22. Àádọ́rin (70) péré ni àwọn baba ńlá a yín tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì, ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín ti mú un yín pọ̀ síi ní iye bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.