1. Olúwa, Olúwa wa,orúkọ Rẹ̀ ti tó tóbi tó ní gbogbo àyé!Ìwọ ti gbé ògo Rẹ̀ gaju àwọn ọ̀run lọ.
2. Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmúni o ti yan ìyìnnítorí àwọn ọ̀ta Rẹ,láti pa àwọn ọ̀ta àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
3. Nígbà tí mo ro ọ̀run Rẹ,iṣẹ́ ìka Rẹ,òṣùpá àti ìràwọ̀,tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
4. kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa Rẹ̀,ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú Rẹ̀?
5. Ìwọ ṣeé ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju ẹ̀dá ọ̀run lọìwọ sì dée ní adé ògo àti ọlá.
6. Ìwọ mu-un jọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ;ìwọ si fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀: