Jóṣúà 15:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ààlà tí ó yípo láti Báálà lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí okè Séírì, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jéárímù (tí íṣe, Késálónì), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Bẹti-Sẹ́mẹ́sì, ó sì kọja lọ sí Tímínà.

11. Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ékírónì, ó sì yípadà lọ sí Síkerónì, ó sì yípadà lọ sí Okè Báálà, ó sì dé Jábínẹ́ẹ́lì, ààlà náà sì parí sí òkun.

12. Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbégbé Òkun ńlá.Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Júdà ní agbo ilé wọn.

13. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Jóṣúà, ó fi ìpín fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, ipin ní Júdà-Kiriati Áríbà, tí í ṣe Hébúrónì. (Áríbà sì ní baba ńlá Ánákì.)

14. Kélẹ́bù sì lé àwọn ọmọ Ánákì mẹ́ta jáde láti Hébúrónì-Ṣéṣáyì, Áhímónì, àti Tálímáì-ìran Ánákì.

15. Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Débírì (tí à ń pè ní Kiriati Séferì tẹ́lẹ̀).

16. Kélẹ́bù sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Ákísà fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati Séférì, tí ó sì gbà á ní ìgbeyàwó.”

17. Ótíniẹ́lì ọmọ Kénásì, arákùnrin Kélẹ́bù, sì gbà á, báyìí ni Kélẹ́bù sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Ákísà fún un ní ìyàwó.

Jóṣúà 15