11. Èmi kún fún ìbínú Olúwa, èmi kò sì le è pa á mọ́ra.“Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àtisórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kórawọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a òmú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbótí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.
12. Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,oko wọn àti àwọn aya wọn,nígbà tí èmi bá na ọwọ́ misí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”ni Olúwa wí.
13. “Láti orí ẹni tí ó kéré sí oríẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọnni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè,àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀sì kún fún ẹ̀tàn.
14. Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyànmi bí ẹni pé kò tó nǹkan.Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà’,nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.
15. Ojú há a tì wọ́n nítorí ìwàìríra wọn bí? Rárá, wọn kòní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní ooru ìtìjúNítorí náà, wọn ó ṣubú láàrinàwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọnlulẹ̀ nígbà tí mo bá fìyà jẹ”wọ́n ni Olúwa wí.
16. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Ẹ dúró sí ìkòríta, kí ẹ sì wò,ẹ bere fún ipa ìgbàanì, ẹ bèèrèọ̀nà dáradára nì, kí ẹ sì wọinú rẹ, ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmifún ọkàn yín.Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rin nínú rẹ.’
17. Èmi yan olùsọ́ fún un yín,mo sì wí pé:‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’
18. Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdèkíyèsí, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìíohun tí yóò sẹlẹ̀ sí wọn.
19. Gbọ́, ìwọ ayé! Mò ń múìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyànwọ̀nyí, eṣo ìrò inú wọn, nítoríwọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sìti kọ òfin mi sílẹ̀.
20. Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràríláti ṣébà wá, tàbí eso dáradáraláti ilẹ̀ jínjìn réré? Ọrẹ sísun yínkò ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ẹbọ yín kò sì wù mí.”