Jẹ́nẹ́sísì 8:2-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Gbogbo ìṣun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró.

3. Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yín àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà.

4. Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ ṣórí òkè Árárátì.

5. Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹ́wàá, orí àwọn òkè sì farahàn.

6. Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Nóà sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀.

7. Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti ṣẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀.

8. Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Nóà. Nóà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀.

10. Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀.

11. Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àsáálẹ́, ó já ewé igi ólífì tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Nóà mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀.

12. Nóà tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.

13. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Nóà sì sí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ.

14. Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ilẹ̀ ti gbẹ pátapáta.

15. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Nóà pé.

Jẹ́nẹ́sísì 8