1. Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Ádámù.Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run.
2. Ó dá wọn ní akọ àti abo, ó sì súre fún wọn. Nígbà tí ó dá wọn tan ó pè wọ́n ní “ènìyàn.”
3. Nígbà tí Ádámù di ẹni Àádóje ọdún (130), ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣétì.
4. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Ṣétì, ó tún wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
5. Àpapọ̀ ọdún tí Ádámù gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-ọgbọ̀n (930), ó sì kú.
6. Nígbà tí Ṣétì pé àrùnlélọ́gọ́rùn ún ọdún (105), ó bí Énọ́sì.
7. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Énọ́sì, ó sì gbé fún ẹgbẹ̀rin-ó-lé-méje ọdún (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
8. Àpapọ̀ ọdún Ṣẹ́tì sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-méjìlá (912), ó sì kú.
9. Nígbà tí Énọ́sì di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún (90) ni ó bí Kénánì.
10. Lẹ́yìn tí ó bí Kénánì, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin-ọdún-ó-lé-mẹ́ẹ̀dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin.
11. Àpapọ̀ ọdún Énọ́sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-márùn-ún (905), ó sì kú.
12. Nígbà tí Kénánì di àádọ́rin ọdún (70) ni ó bí Máhálálélì:
13. Lẹ́yìn tí ó bí Máhálálélì, ó wà láàyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rín ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbínrin.
14. Àpapọ̀ ọjọ́ rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ó-lé-mẹ́wàá ọdún (910), ó sì kú.
15. Nígbà tí Máhálálélì pé ọmọ àrúnlélọ́gọ́ta ọdún (65) ni ó bí Járédì.
16. Máhálálélì sì gbé fún ẹgbẹ̀rin-ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Járédì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
17. Àpapọ̀ iye ọdún rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-márùn-ún (895), ó sì kú.
18. Nígbà tí Járédì pé ọmọ ọgọ́jọ-ó-lé-méjì ọdún (162) ni ó bí Énọ́kù.
19. Lẹ́yìn èyí, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800) ó sì bí àwọn ọmọkúnrin àti ọmọbìnrin.
20. Àpapọ̀ ọdún rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-méjìdínlógójì (962); ó sì kú.
21. Nígbà tí Énọ́kù pé ọmọ ọgọ́ta-ó-lé-márùn ọdún (65) ni ó bí Mètúsẹ́là.
22. Lẹ́yìn tí ó bí Mètúsẹ́là, Énọ́kù sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
23. Àpapọ̀ ọjọ́ Énọ́kù sì jẹ́ irínwó-dín-márùndínlógójì-ọdún (365).
24. Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn: a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ.
25. Nígbà tí Mètúsẹ́là pé igba-ó-dín-mẹ́talá ọdún (187) ní o bí Lámékì.
26. Lẹ́yìn èyí ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin-dín-méjìdínlógún ọdún (782), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
27. Àpapọ̀ ọdún Mètúsẹ́là jẹ́ ẹgbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-mọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú.
28. Nígbà tí Lámékì pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án (182) ni ó bí ọmọkùnrin kan.
29. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Nóà, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi gégùn-ún.”
30. Lẹ́yìn tí ó bí Nóà, Lámékì gbé fún ẹgbẹ̀ta-ó-dín-márùn-ún ọdún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
31. Àpapọ̀ ọdún rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin-ọdún-ó-dín-mẹ́talélógún (777), ó sì kú.
32. Lẹ́yìn tí Nóà pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500) ni ó bí Ṣémù, Ámù àti Jáfétì.