Jẹ́nẹ́sísì 43:21-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ṣùgbọ́n níbi tí a ti dúró ní ọ̀nà láti sùn ní alẹ́, nígbà tí a tú àpò oúnjẹ wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá owó oúnjẹ tirẹ̀ tí ó rà lẹ́nu àpò láì lé, láì dín. Nítorí náà òun nìyí, a ti mu-un padà wá pẹ̀lú wa.

22. A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ láti fi ra oúnjẹ. A ò mọ ẹni tí ó fi owó wa sí ẹnu àpò.

23. Ó dáhùn pé, “Ó dára, ẹ má bẹ̀rù, Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run baba yín ni ó fi ìsúra sí inú àpò yín; mo rí owó tí ẹ san gbà.” Nígbà náà ni ó mú Símónì jáde tọ̀ wọ́n wá.

24. Ìránṣẹ́ náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Jósẹ́fù, ó fún wọn ní omi láti fi wẹ ẹsẹ̀ wọn nu, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn lóúnjẹ pẹ̀lú.

25. Wọ́n pèṣè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Jósẹ́fù di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán.

26. Nígbà tí Jósẹ́fù dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún-un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.

27. Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láàyè?”

28. Wọ́n dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ, baba wa sì wà láàyè, àlàáfíà sì ni ó wà pẹ̀lú.” Wọn sì tẹríba láti bọ̀wọ̀ fún un.

29. Bí ó ti wo yíká tí ó sì rí Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan-an. Ó béèrè lọ̀wọ̀ wọn pé, “Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí?” Ó sì tún wí pe, “Kí Ọlọ́run kí ó sàánú fún ọ, ọmọ mi”

30. Ọkàn rẹ̀ sì fà sí i gidigidi nígbà tí ó rí arákùnrin rẹ̀, nítorí náà Jósẹ́fù yára jáde láti wá ibi tí ó ti le sunkún. Ó lọ sí iyàrá rẹ̀, ó sì sunkún níbẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 43