1. Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Fáráò lá àlá: ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Náílì.
2. Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko.
3. Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Náílì, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà.
4. Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Fáráò jí.
5. Ó sì tún padà sùn, ó sì lá àlá mìíràn: ó rí siírì ọkà méje tí ó kún, ó yó'mọ, ó sì dára, ó sì jáde lára igi ọkà kan ṣoṣo.
6. Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yó'mọ, afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù.
7. Àwọn sìírì ọkà méje tí kò yó'mọ (ọmọ rẹ̀ kò tóbi) wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yó'mọ (ọmọ rẹ̀ tóbi) mì. Nígbà náà ni Fáráò jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni.