Jẹ́nẹ́sísì 3:7-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn.

8. Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárin àwọn igi inú ọgbà.

9. Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?”

10. Ó dáhùn pé, “Mo gbúrò ó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí nítorí pé, mo wà ní ìhòòhò, mo sì fi ara pamọ́.”

11. Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èṣo igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?”

12. Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èṣo igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”

13. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?”Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.”

14. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí,“Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìnàti gbogbo ẹran igbó tó kù lọ!Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́,ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

15. Èmi yóò sì fi ọ̀tásí àárin ìwọ àti obìnrin náà,àti sí àárín irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ obìnrin náà;òun yóò fọ́ orí rẹìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

16. Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé:“Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ;ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ.Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí,òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.”

17. Ọlọ́rún sì wí fún Ádámù pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èṣo igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’“Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ;nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀,ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

18. Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èsùsú fún ọ,ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ.

19. Nínú òógùn ojú rẹni ìwọ yóò máa jẹuntítí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀,nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá;erùpẹ̀ ilẹ̀ ṣáà ni ìwọ,ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”

20. Ádámù sì sọ aya rẹ̀ ní Éfà nítorí òun ni yóò di ìyá gbogbo alààyè.

21. Olúwa sì dá ẹ̀wù awọ fún Ádámù àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.

22. Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èṣo igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láàyè títí láéláé.”

23. Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá.

Jẹ́nẹ́sísì 3