1. Nígbà ti Ísáákì di arúgbó, ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran. Ó pe Ísọ̀ àkọ́bí rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Ọmọ mi”,Ísọ̀ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
2. Ísáákì sì wí pé, “Nísinsin yìí mo di arúgbó, èmi kò sì mọ ọjọ́ tí èmi yóò kú.
3. Nítorí náà, mú ohun èlò ọdẹ rẹ—apó àti ọrún—nísinsin yìí kí o sì lọ pa ẹran wá fún mi nínú igbó.
4. Kí o sì ṣe ẹran àdídùn fún mi, irú èyí tí mo fẹ́ràn kí o gbe wá fún mi kí n jẹ, kí n sì súre fún ọ kí n tó kú.”
5. Ṣùgbọ́n Rèbékà ń rfetí léko gbọ́ nígbà tí Ísáákì ń bá Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nítorí náà, nígbà ti Ísọ̀ ti ṣe ọdẹ lọ sínú igbó,
6. Rèbékà sọ fún Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń bá ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀ pé,
7. ‘Pa ẹran fún mi wá, kí o sì se oúnjẹ àdídùn fún mi láti jẹ, kí n baà le súre fún ọ níwájú Olúwa kí èmi tó kú.’
8. Nísinsin yìí ọmọ mi, gbọ́ tèmi kí o sì ṣe ohun tí èmi yóò wí fún ọ:
9. Lọ sínú agbo ẹran, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì, kí ó lè ṣe oúnjẹ́ àdídùn fún baba rẹ, irú èyí tí ó fẹ́ràn dáradára.
10. Ìwọ yóò sì gbé e tọ baba rẹ lọ, kí òun baà lè jẹ ẹ́, kí ó sì súre fún ọ kí ó tó kú.”
11. Jákọ́bù sì wí fún Rèbékà ìyá rẹ̀ pé, “Ṣùgbọ́n Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi jẹ́ ènìyàn onírun lára bẹ́ẹ̀ alára ọ̀bọ̀rọ́ ni mi,