Jẹ́nẹ́sísì 2:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.

23. Ọkùnrin náà sì wí pé,“Èyí ni egungun láti inú egungun miàti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;‘obìnrin’ ni a ó máa pè énítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”

24. Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

25. Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòòhò, ojú kò sì tì wọ́n.

Jẹ́nẹ́sísì 2