Ísíkẹ́lì 11:9-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. N ó lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, n ó sì fà yín lé àlejò lọ́wọ́, n ó sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí.

10. Nípa idà ni ẹ ó ṣubú, n ó sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Ísírẹ́lì. Nígbà náà lẹ ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

11. Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀; N ó ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Ísírẹ́lì.

12. Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀ èdè tó yí yín ká.”

13. Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pélátíà ọmọ Bénáyà kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Áà! Olúwa, Ọlọ́run! Ṣé o fẹ́ pa ìyókù Ísírẹ́lì run pátapáta ni?”

14. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá:

15. “Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì pátapáta, ni àwọn ará Jérúsálẹ́mù ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí Olúwa, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’

16. “Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀ èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, n ó jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’

17. “Nítorí náà, sọ pé: ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì padà.’

18. “Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn ó sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà kúrò.

19. N ó fún wọn ní ọ̀kan kan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn; N ó mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, n ó sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran.

20. Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

21. Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sórí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”

22. Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lókè orí wọn.

Ísíkẹ́lì 11