13. Nígbà tí wọ́n sì kíyèsí ìgboyà Pétérù àti Jòhánù, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jésù gbé.
14. Nígbà tí wọ́n sì ń wo ọkùnrin náà tí a mú láradá, tí ó bá wọn dúró, wọn kò rí nǹkan wí sí i.
15. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sì ti pàṣẹ pé kí wọn jáde kúrò ní ìgbìmọ̀, wọ́n bá ara wọn gbérò.
16. Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ àmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerúsálémù; àwa kò sì lè ṣe èyí.
17. Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tàn kálẹ̀ ṣíwájú mọ́ láàrin àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́.”
18. Wọ́n sì pè wọ́n, wọ́n pàsẹ fún wọn, kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni rárá mọ́ ní orúkọ Jésù.
19. Ṣùgbọ́n Pétérù àti Jòhánù dáhùn, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú Ọlọ́run láti gbọ́ tiyín ju ti Ọlọ́run lọ ẹ gbà á rò.
20. Àwa kò lè sàìmá sọ ohun tí àwa ń rí, tí a sì ti gbọ́.”
21. Nígbà tí wọ́n sì kìlọ̀ fún wọn sí i, wọn fi wọ́n sílẹ̀ lọ, nígbà tí wọn kò ì tí ì rí nǹkan tí wọn ì bá fi jẹ wọ́n ní ìyà, nítorí àwọn ènìyàn; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n yin Ọlọ́run lógo fún ohun tí ó ṣe.
22. Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ àmì ìmúlaradà, ju ẹni-ogoji ọdún lọ.
23. Nígbà tí wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà sọ fún wọn.
24. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, àti òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.
25. Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dáfídì baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé:“ ‘E é ṣe tí àwọn kéférì fi ń bínú,àti tí àwọn ènìyàn ń gbérò ohun asán?
26. Àwọn ọba ayé dìde,àti àwọn ìjòyè kó ara wọnjọ sí Olúwa,àti sí Ẹni-Àmìn òróró rẹ̀.’
27. Àní nítòótọ́ ní Hẹ́rọ́dù, àti Pọ́ńtíù Pílátù, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jésù Ìrànṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi òróró yàn,
28. Láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣẹ.
29. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsí ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.
30. Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradà, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jésù Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”
31. Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọ pọ̀ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.