27. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru ọjọ́ kẹrìnlá, bí a ti ń gbé wa kọjá lọ láàrin òkun Ádíríà, láàrin ọ̀gànjọ́ àwọn atukọ̀ fura pé, àwọn súnmọ́ etí ilẹ̀ kan:
28. Nígbà tí wọ́n sì wọn òkun, wọ́n rí i ó jìn ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún ṣíwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn òkun, wọn rí i pé ó jìn ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógùn.
29. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ro mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí-ọkọ̀, wọ́n ń rétí òjúmọ́.
30. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ ìgbàjá kalẹ̀ sí ojú òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀.
31. Pọ́ọ̀lù wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!”
32. Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun gé okùn ìgbàjá, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣúbu sọ́hun.
33. Nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, Pọ́ọ̀lù bẹ gbogbo wọn kí wọn jẹun díẹ̀, ó wí pé, “Òní ni ó di ìjẹrìnlá tí ẹ̀yin ti ń rétí, ti ẹ kò dẹkun gbígbaàwẹ̀, tí ẹ kò sì jẹun.
34. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, kí ẹ jẹun díẹ̀, nítorí èyí ni fún ìgbàlà yín: nítorí irun kan kí yóò rẹ́ kúrò lórí ẹnìkan yín.”
35. Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì mú àkàrà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn: nígbà tí ó si bù ú, ó bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ.
36. Nígbà náà ni gbogbo wọn sì daráyá, àwọn pẹ̀lú sì gba oúnjẹ,
37. Gbogbo wa tí ń bẹ nínú ọkọ̀-okun náà sì jẹ́ ọ̀rìnlúgba ènìyàn ó dín mẹ́rin (276).
38. Nígbà tí wọn jẹun yó tan, wọn bẹ̀rẹ̀ sí mu ọkọ̀-okun náà fúyẹ́, nípa kíkó àlìkámà dà sí omi.
39. Nígbà tí ilẹ̀ sí mọ́, wọn kò mọ́ ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n wọn rí apá odò kan tí ó ní èbúté, níbẹ́ ni wọ́n gbérò, bóyá ó le ṣe é ṣe láti mu ọkọ̀ gúnlẹ̀.
40. Nígbà tí wọ́n sì gé ìdákọ̀ró kúrò, wọn jù wọn sínú òkun, lẹ́sẹ̀kan náà wọn tú ìdè-ọkọ̀, wọn sì ta ìgbòkùn iwájú ọkọ̀ sí afẹ́fẹ́, wọn sì wakọ̀ kọjú sí etí-òkun.
41. Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí òkun méjì pàde, wọn fi orí-ọkọ̀ sọlẹ̀: iwájú rẹ̀ sì kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin, ó dúró, kò lè yí, ṣùgbọ́n agbára rírú omi bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ìdí ọkọ̀ náà.
42. Èrò àwọn ọmọ-ogun ni ki a pá àwọn òǹdè, kí ẹnikẹ́ni wọn má ba à wẹ̀ jáde sá lọ.
43. Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún ń fẹ́ gba Pọ́ọ̀lù là, ó kọ èrò wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn tí ó lè wẹ̀ kí wọn bọ́ sí òkun lọ sì ilẹ̀.
44. Àti àwọn ìyókú, òmìíràn lórí pátakó, àti omíràn lórí àwọn igi tí ó ya kúrò lára ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe tí gbogbo wọn yọ, ní àlàáfíà dé ilẹ́.