Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Fílípì, Ìlú kan tí (àwọn ara Róòmù) tẹ̀dó tí í ṣe olú ìlú yìí fún ọjọ́ mélòókán.

13. Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókóò, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ ṣọ̀rọ̀.

14. Àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Lìdíà, tí ó ń ta àwọn aró ẹlẹ́ṣè àlùkò, gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ọkàn ẹni tí Olúwa ṣí láti fetísì ohun tí a tí ẹnu Pọ́ọ̀lù sọ.

15. Nígbà tí a sí bamitíìsì rẹ̀, àti àwọn ara ilé rẹ̀, ó bẹ̀ wá, wí pé, “Bí ẹ̀yin bá kà mí ni olóòtọ́ sí Olúwa, ẹ wá si ilé mi, kí ẹ sí wọ̀ níbẹ̀!” O sí rọ̀ wá.

16. Bí àwa tí nlọ ṣí ibi àdúrà náà, ọmọbìnrin kan tí o ní ẹ̀mí ìwosẹ́, pàdé wa, ẹni tí ó fi àfọ̀ṣẹ mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀:

17. Òun náà ni ó ń tọ Pọ́ọ̀lù àti àwa lẹ́hìn, ó sì ń kígbe, pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni ìránṣẹ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yin!”

18. Ó sì ń ṣe èyí lọ́jọ́ púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí inú Pọ́ọ̀lù bàjẹ́, tí ó sì yípadà, ó wí fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jéṣù Kíríṣítì kí o jáde kúrò lára rẹ̀!” Ó sí jáde ni wákàtí kan náà.

19. Nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ sì ríì pé, ìgbẹ́kẹ̀lé èrè wọn pin, wọ́n mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà, wọn sì wọ́ wọn lọ sí ọjà tọ àwọn aláṣẹ lọ;

20. Nígbà tí wọ́n sì mú wọn tọ àwọn onídájọ́ lọ, wọ́n wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí í ṣe Júù, wọ́n ń yọ ìlú wa lẹ́nu jọjọ;

21. Wọ́n sí n kọ́ni ní àṣà tí kò yẹ fún wa, àwa ẹni tí í ṣe ara Romu, láti gbà àti láti tẹ̀lé.”

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16