2. Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!”
3. Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.
4. Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn mẹ́jẹ̀èjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Séléúkíà; láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀-ojú omi lọ sí Sáípúrọ́sì.
5. Nígbà ti wọ́n sì wà ni Sálámísì, wọ́n ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní sínágọ́gù àwọn Júù. Jòhánù náà sì wà pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún ìránṣẹ́ wọn.
6. Nígbà tí wọ́n sì la gbogbo erékùṣù já dé Páfọ̀, wọ́n rí ọkùnrin kan, oṣó, wòlíì èké, Júù, orúkọ ẹni ti ó ń jẹ́ Baa-Jésù.
7. Ó wà lọ́dọ̀ Ségíù Páúlúsì baálẹ̀ ìlú náà, amòye ènìyàn. Òun náà ni ó ránṣẹ́ pe Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù, nítorí tí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
8. Ṣùgbọ́n Élímù oṣó (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀) takò wọ́n, ó ń fẹ́ pa báalẹ̀ ni ọkàn dà kúrò ni ìgbàgbọ́.
9. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ti a ń pè ni Pọ́ọ̀lù, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Ẹ́límù, ó sì wí pé,
10. “Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà-ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ Èṣù, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po?