Ìṣe Àwọn Àpósítélì 11:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn àpósítélì àti àwọn arákùnrin ti ó wà ni Jùdíà sì gbọ́ pé àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

2. Nígbà tí Pétérù sì gòkè wá sí Jerúsálémù, àwọn ti ìkọlá ń bá a wíjọ́

3. wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”

4. Ṣùgbọ́n Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí i là á yé wọn lẹ́sẹẹsẹ, wí pé,

5. “Èmi wà ni ìlú Jópà, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi.

6. Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko ìgbẹ́, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run.

7. Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, ‘Dìde, Pétérù: máa pa, kí ó sì máa jẹ.’

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 11