Deutarónómì 9:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ní Hórébù ẹ mú kí Olúwa bínú, títí débi pé ó fẹ́ run yín.

9. Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba sílétì òkúta, sílétì májẹ̀mú ti Olúwa ti bá a yín dá. Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mumi.

10. Olúwa fún mi ní òkúta méjì tí a fi ìka Ọlọ́run kọ. Lórí wọn ni a kọ àwọn òfin tí Ọlọ́run sọ fún un yín lórí òkè láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ sí.

11. Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, Olúwa fún mi ní sílétì òkúta méjì, sílétì òkúta májẹ̀mú náà.

12. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìnín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Éjíbítì ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kíá, nínú àṣẹ mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.”

13. Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé alágídí ènìyàn gbáà ni wọ́n.

14. Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀ jù wọ́n lọ.”

15. Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí okè náà wá, orí òkè tí o ń yọná. Àwọn sílétì májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi.

16. Gbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un yín.

17. Bẹ́ẹ̀ ni mó ju síléètì méjèèjì náà mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ lójú u yín.

Deutarónómì 9