Deutarónómì 9:24-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín ni ẹ ti ń sọ̀tẹ̀ sí Olúwa.

25. Mo ti wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé Olúwa sọ pé Òun yóò pa yín run.

26. Mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Olúwa Olódùmarè, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní ogún rẹ tí o ti ràpadà, nípa agbára rẹ tí o sì fi agbára ńlá mú wọn jáde láti Éjíbítì wá.

27. Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù. Fojú fo orí kunkun àwọn ènìyàn yìí, pẹ̀lú ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

28. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti mú wa jáde wá yóò wí pé, ‘Torí pé Olúwa kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ náà tí ó ti ṣèlérí fún wọn, àti pé ó ti kórìíra wọn, ni ó fi mú wọn jáde láti pa wọ́n ní ihà.’

29. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn rẹ ni wọ́n, ogún rẹ tí o ti fi ọwọ́ agbára rẹ àti nínà ọwọ́ rẹ mú jáde.”

Deutarónómì 9