Deutarónómì 8:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ kíyèsí láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ báà le yè kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí Olúwa fìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín.

2. Ẹ rántí bí Olúwa Ọlọ́run yín ti tọ́ ọ yín sọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ní ihà fún ogójì ọdún wọ̀nyí láti tẹ orí i yín ba àti láti dán an yín wò kí ó báà le mọ bí ọkàn yín ti rí, bóyá ẹ ó pa òfin rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

3. Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi mánà bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó báà lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò wà láàyè nípa oúnjẹ nìkan, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu Olúwa wá.

4. Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọ yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹṣẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà.

5. Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín.

6. Torí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀.

7. Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń ṣàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.

8. Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà bálì, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pómégíránátì, òróró ólífì àti oyin.

9. Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá.

10. Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin Olúwa Ọlọ́run yín fún pípèṣè ilẹ̀ rere fún un yín.

11. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.

12. Kí ó má baà jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀,

Deutarónómì 8