Deutarónómì 27:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládúgbò o rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

18. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó si afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

19. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àléjò, aláìní baba tàbí opó”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

Deutarónómì 27