Ámósì 9:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo rí Olúwa, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé:“Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùnkí àwọn òpó kí ó lè mìfọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyànàwọn tí ó sẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa,Ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbéẸni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà.

2. Bí wọ́n tilẹ wa ilẹ lọ sí ìpò òkúLáti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́nBí wọ́n tilẹ̀ gun òkè ọ̀run lọ,láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀kalẹ̀.

3. Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Kámẹ́lì,èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀.Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìṣàlẹ̀ òkun,láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán.

4. Bí wọ́n tilẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní iwájú àwọn ọ̀tá wọnláti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà kí ó ṣá wọn pa.Èmi yóò sì tẹ ojú mi mọ́ wọn fún ìbí,kì í sì í se fún rere.”

5. Olúwa, Ọlọ́run AlágbáraẸni ti ó fi ọwọ́ kan ìlẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì sọ̀fọ̀Gbogbo orílẹ̀ èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Náìlìti wọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Éjíbítì.

Ámósì 9