7. Olúwa sọ di talákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀;ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.
8. Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá,ó gbé alágbe sókè láti orí òkítì eérú wá,láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé,láti mu wọn jogún ìtẹ́ ogo:“Nítorí pé ọ̀wọ̀n ayé ti Olúwa ni,ó sì ti gbé ayé ka orí wọn
9. Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.
10. A ó fọ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;láti ọrun wá ni yóò sánààrá sí wọn; Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,yóò si gbé ìwo ẹni-àmì-òróró rẹ̀ sókè.”
11. Elikánà sì lọ sí Rámà sí ilé rẹ̀, Ọmọ náà sì ń ṣe ìráńṣẹ́ fún Olúwa níwájú Élì àlùfáà.
12. Àwọn ọmọ Élì sì jẹ́ ọmọ Bélíálì; wọn kò mọ Olúwa.
13. Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀.
14. Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí Kẹ́tìlì tàbí òdù, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣílò.
15. Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfàá; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò se tútù.”
16. Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́;” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.”
17. Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùrin náà sì tóbi gidigidi níwájú Olúwa: nítorí tí ènìyàn kórìíra ẹbọ Olúwa.
18. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì ń ṣe ìráńṣẹ́ níwájú Olúwa, ọmọdé, ti a wọ̀ ní éfódì ọ̀gbọ̀.
19. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mu wá fún un lọdọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún.
20. Élì súre fún Elikánà àti aya rẹ̀ pé, “Kí Olúwa fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún Olúwa.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn.
21. Olúwa si bojú wo Hánà, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Sámúẹ́lì ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú Olúwa.
22. Élì sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.
23. Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri “Èétirí tí èmi fi ń gbọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín? Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.
24. Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí kì ṣe ìròyìn rere èmi gbọ́; ẹyin mú ènìyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀.
25. Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí Olúwa, tani yóò bẹ̀bẹ̀ fún un?” Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí Olúwa ń fẹ́ pa wọ́n.